Nigeria’sTwitter ban: Orílẹ̀-èdè Amẹrika pé kí Naijiria fòpin sí fifofinde Twitter.

Orílẹ̀-èdè Amẹrika tí bu ẹnu àtẹ́ lu bí ìjọba Nàìjíríà ṣe fòfinde lilo òpó ikansiraẹni Twitter tí wọ́n sì pàṣẹ láti fi ẹnikẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ jófin tó fi mọ́ àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn.
Wọ́n ké sí ìjọba láti ṣe àtúngbéyèwò ìpinnu wọn.

“Dídí àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́wọ́ láti kó ìròyìn jọ àti láti sọ èrò ọkàn wọ́n àti nǹkan tí wọn mọ̀ síta kò ní ààyè nínú ètò ìṣèjọba àwa arawa.
Ànfàní láti lè sọ èrò ọkàn ẹni àti láti mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ tó n lọ lórí ayélujára àti láyìíká jẹ́ ìpílẹ̀ fún eto ijoba àwa arawa tó ní ìlọsíwájú ni àwùjọ, agbenusọ ilẹ̀ Amerika Ned Price ló sọ èyí nínú àtẹ̀jáde.

Ẹ̀yin iléesẹ́ ìròyìn gbogbo ní Nàìjíríà, Ẹ dẹ́kun líló ‘Twitter’ bí bẹ́ẹ̀ kọ́…- NBC
Price fi kún pé àjọ tó ń mójútó ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ (NBC) tí pa á láṣẹ fún àwọn oniroyin ilé iṣẹ́ amóhùmáwòrán àti rẹ́díò láti dẹkùn lilo Twitter.

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fòfinde Twitter láìsí gbedeke ọjọ́ lẹ́yìn tí ilé iṣẹ́ náà yọ ọ̀rọ̀ kan tí ààrẹ sọ pé ó tẹ òfin Twitter lójú mọ́lẹ̀, pàápàá julọ èyí tí ààrẹ sọ pé èdè tí àwọn tó ń dá ìlú ru gbọ́ ni òun yóò fi bá wọn sọ̀rọ̀.

Lẹyin èyí ni àwọn ilé iṣẹ́ tó ń sagbateru ìbára ẹni sọ̀rọ̀ gbogbo náà gbégidínà lílò rẹ̀ fún àwọn oníbàráà wọn tí ìjọba pẹ̀lú sì tún kesi Twitter àti àwọn òpó ikansiraeni tó kù lọ́jọ́ru pé kí wọ́n wá gba ìwé àṣẹ láti ṣiṣẹ́ ni Nàìjíríà

Ni báyìí ilé iṣẹ́ Twitter náà tí fi àwọn ènìyàn lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn ń sapá lati mú kí àwọn ará ìlú láǹfààní láti túbọ̀ máa lo o.

Ilé iṣẹ́ Twitter àti àjọ ajafẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn Amnesty International náà ṣàlàyé pé fifofinde Twitter jẹ́ nǹkan tó jẹ àwọn lógún gidi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *