Home » Asiiri Nla: Lẹyin to bimọ tuntun tan, Liz Anjọrin ni ibẹfa lo wu mi ki n tun bi

Asiiri Nla: Lẹyin to bimọ tuntun tan, Liz Anjọrin ni ibẹfa lo wu mi ki n tun bi

Gbajugbaja oṣere tiata wa, to tun jẹ oniṣowo pataki, Alaaja Aishat Elizabeth Lawal ti gbogbo aye mọ si Liz Anjọrin ti sọ pe ibẹfa lo wu oun bi lẹyin ọmọ tuntun toun ṣẹṣẹ bi yii, bẹẹ lo fidi ẹ mulẹ pe oun ko fẹ ki kinni ọhun pẹ rara.

Oṣere nla yii ti awọn eeyan tun mọ si Ẹgandogo tu asiiri yii fun Gbelegbọ lọsan -an ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii. Oṣere yii nla yii ni adura ti oun gba si Ọlọrun ni pe ko fun oun lọmọ mẹfa lẹẹkan ṣoṣo, ki oun le pa gbogbo awọn ọta oun lẹnu mọ, o loun fẹẹ ṣeruba awọn ọmọ ọta oun pẹlu awọn ibẹfa ti oun tọrọ yii.

Nipa idi to fẹẹ fi ṣayẹyẹ ikomọ ọmọ ẹ, iyẹn Florida lawọn ipinlẹ mẹwaa lorileede Amẹrika, oṣere yii sọ pe awọn ololufẹ oun ni wọn ṣagbẹteru ayẹyẹ naa, o ni o ya oun gan-an lẹnu nigba ti wọn sọ fun oun nipa awọn ibi ti ayẹyẹ naa ti fẹẹ waye.O loun gan-an ro o lọkan ara oun pe bawo loun se fẹẹ rin irin-ajo naa, ṣugbọn niwọn igba to ti jẹ pe oun ti awọn ololufẹ oun beere fun niyẹn, o di dandan ki oun gba fun wọn.

O ni oun tawọn ololufẹ oun yii sọ ni pe ọmọ tuntun yii, Florida ki i ṣe eeyan kekere ninu aye, awọn si gbọdọ ṣayẹyẹ nla fun ẹni nla to ṣẹṣẹ de ile aye ọhun.     Bẹẹ lo fi kun ọrọ ẹ pe ọmọ tuntun yii tunbọ jẹ ki ifẹ oun ati ọkọ oun rinlẹ si i,o fi kun ọrọ ẹ pe gbogbo ariwo ti awọn ọta oun pa kiri yii, ko tu irun kankan lara oun ati baale oun. O ni bi wọn ṣe sọrọ oun kiri yii, ni Ọlọrun tun n gbe oun ga si i 

Bakan naa la a bi i nipa bi inu akọbi ẹ, Oluwarotimi ṣe dun to nigba to bimọ l e e, alaye ti to ṣe nipe inu ẹ dun gidi gan-an, o ni bo tilẹjẹ pe Florida si kere, ṣugbọn o ti han pe ifẹ nla lo wa laarin oun ati ikoko naa.              

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *