Home » Mọ̀ nípa Bolaji Agbede ti Access Bank fi rọ́pò olóògbé Herbert Wigwe gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà tuntun

Mọ̀ nípa Bolaji Agbede ti Access Bank fi rọ́pò olóògbé Herbert Wigwe gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà tuntun

Ileeṣe Access Holdings Plc ti kede alakoso ati oludasilẹ agba tuntun fun ileeṣẹ naa lẹyin iku Herbert Wigwe to padanu ẹmi rẹ siluu Amẹrika.

Ọjọ Aje, ọsẹ yii ni igbimọ awọn alakoso ileeṣẹ naa gbe ikede yii sita – ọjọ keji lẹyin iku Herbert Wigwe to jẹ alakoso tẹlẹ.

Arabinrin Bọlaji Agbẹdẹ ni orukọ ẹni naa ti wọn sọ pe oun ni yoo ṣi maa tẹsiwaju.

Wigwe ati awọn marun-un miran ni wọn ku sinu ijamba ọkọ baluu ẹlikọpita ni alẹ ọjọ Ẹti to kọja.

Ijamba naa gba ẹmi Wigwe, iyawo ati ọmọ rẹ kan, to fi mọ awọn miran ti wọn jọ wa ninu rẹ.

Awọn alakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ aabo irin-ajo, National Transport Safety Board (NTSB) nigba ti wọn n sọrọ nipa iṣẹlẹ naa lọjọ Aiku to kọja yii jẹ ko di mimọ pe ọkọ baluu agberapa Airbus Helicopters EC-130 lo jabọ lule niluu California to wa nitosi ẹnubode Nevada.

Ọkan lara awọn alakoso NTSB, Michael Graham ati oluwadi kan, Aaron Sours, sọ pe iwadii fihan pe lara nnkan to ṣokunfa ijamba naa ni pe ojo n rọ lọwọ lasiko ti ijamba naa waye.

“Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe bi oju ọjọ ṣe ri lasiko naa, ati pe ojo to n rọ ati iji to n ja lo fa ohun to ṣẹlẹ.”

Nigba ti awọn eeyan ṣi n kẹdun lẹyin ti awọn igbimọ alakoso fidi rẹ mulẹ pe Herbert Wigwe ti jade laye, ni wọn tun kede Arabinrin Agbẹdẹ gẹgẹ bi adele.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *