Home » Baba Ijesha: Ta ló yọ ojú òpó ‘GoFundMe’ tí wọ́n ṣí fún afurasí Olanrewaju Omiyinka kúrò lórí ayélujára?

Baba Ijesha: Ta ló yọ ojú òpó ‘GoFundMe’ tí wọ́n ṣí fún afurasí Olanrewaju Omiyinka kúrò lórí ayélujára?

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le sọ ni pato boya ọgbẹni Oladele Matti to ṣi oju opo naa lo yọ ni tabi ileeṣẹ GoFundMe funra rẹ.

Ṣugbọn iroyin sọ pe igbeṣe naa waye lẹyin ti awọn eeyan kan bẹrẹ si n ṣe ifẹhonuhan lori ayelujara lẹyin ti Matti ṣi oju opo naa tan.

Ṣaaju ni ni wọn ti kọkọ fẹsun kan Baba Ijesha pe o ba ọmọde ni ibalopọ lọna ti ko tọ, eyii to lodi si abala ofin 135, 137, 261, 202, 262 ati 263 to rọ mọ ibalopọ ni ipinlẹ Eko. Asiko ti igbẹjọ naa bẹrẹ ni ọkan lara awọn ololufẹ rẹ to fi orilẹ-ede Ireland ṣebugbe, Oladele Matti ṣi oju opo GoFundMe fun Baba Ijesha pẹlu erongba lati ko €50,000 jọ ko le fi ṣe ẹjọ ọhun

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *