Home » BBC Komla Dumor Award 2022: Iléeṣẹ́ ìròyìn BBC ṣe ìfilọ́lẹ̀ àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor

BBC Komla Dumor Award 2022: Iléeṣẹ́ ìròyìn BBC ṣe ìfilọ́lẹ̀ àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor

BBC wa n ke si awọn akọroyin kaakiri ilẹ Afrika lati forukọ silẹ fun ami ẹyẹ naa, pẹlu erongba lati ṣawari awọn akọroyin to dantọ nilẹ Afrika.

Ẹnikẹni to ba gba ami ẹyẹ naa yoo lo oṣu mẹta ni olu ileeṣẹ iroyin BBC to wa niluu London, nibi ti yoo ti kọ si nipa iṣẹ akọroyin.

Aago mejila oru, ọjọ kẹrindilogun, oṣu Keji, ọdun 2022 ni eto iforukọsilẹ naa yoo wa sopin.

Wọn ṣe agbekalẹ ami ẹyẹ nyii i iranti akọrọroyin BBC ọmọ orilẹ-ede Ghana kan to lamilaaka, fun iṣẹ ribiribi to ṣe gẹgẹ bii akóroyin BBC ko to dagbere faye lẹni ọdun mọkanlelogoji lọdun 2014.

Iyawo rẹ, Kwansema Dumor sọ fun ẹni to ti gba ami ẹyẹ naa kẹyin, Victoria Rubadiri pe inu oun dun fun ipa ti oloogbe naa ni nileeṣẹ iroyin BBC, ati bi wọn ṣe n ṣe iranti rẹ nipa ami ẹyẹ ọhun.

BBC ti wa rọ awọn akọroyin kaakiri ilẹ Afrika lati forukọsilẹ fun anfani lati gba ami ẹyẹ ọhun, eyii ti yoo ṣe ayẹsi awọn akọroyin ni Afrika.
Ẹnikẹni to ba gba ami ẹyẹ naa, yatọ si pe yoo gba idanilẹkọọ nileeṣẹ iroyin BBC ni London, yoo tun ni anfaani lati rinrinajo lọ silẹ Afrika kan lati jabọ iroyin to ba nifẹ si, eyii ti a oo ṣafihan rẹ fun gbogbo agbaye.

Nigba aye rẹ, ipa ti Dumor ko nileeṣẹ iroyin BBC ko kere, BBC si n fi ami ẹyẹ naa ṣe iranti rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Rubadiri ko le ṣe idanilẹkọọ naa lọdun 2020, wọn sun idanilẹkọọ ọhun si 2021.

Lasiko idanilẹkọọ rẹ, o rinriajo lọ si ilu Kinshasa, tii ṣe olu ilu orilẹ-ede Democratic Republic of Congo lati jabọ iroyin nipa aapu to ni ṣe pẹlu irinajo oju popo.

Ọga agba BBC, Tim Davies lo si gbe ami ẹyẹ naa le lọwọ.
Dumor darapọ mọ BBC lọdun 2007 lẹyin to ti kọkọ ṣiṣe lawọn ileeṣẹ iroyin kan ni Ghana, tii ṣe orilẹ-ede rẹ.

Laarin ọdun 2007 si 2009, oun lo maa n tukọ eto Network Africa fun ẹka “BBC World Service”, nigba to kuro nibẹ o darapọ mọ eto “The World Today.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *