Home » Ẹ̀bi tani bí àwọn ajínigbé ṣe ń kọlu àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá?

Ẹ̀bi tani bí àwọn ajínigbé ṣe ń kọlu àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá?

Laipẹ yii ni awọn agbebọn kọlu awọn ọba kan, paapaa ni ipinlẹ Ekiti ati Oyo, ti wọn si pa wọn.

Oriṣiriṣi nnkan si ni awọn araalu sọ pe o fa iru nnkan bẹẹ.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe awọn ọba ti di iwọlẹ laarin ilu, ni awọn kan n sọ pe aibọwọ fun aṣa ninu ilana yiyan ọba ati bi awọn ọba ṣe le huwa lode oni, lo n fa a .

Eyi lo mu ki BBC Yoruba ba awọn ọba alaye mẹta kan sọrọ lori eyi.

Awọn ori ade naa, Ọba Olufemi Ogunleye (Akinale ti Akinale Owu), Oba Adeyemi Obalanlege )Olota ti ilu Ota), ati Oba Taiwo Taiwo (Onipara ti ilu Ipara) lati mọ erongba wọn.

Ninu ọrọ tiẹ, ọba olota sọ pe fifi awọn ẹsin miran rọpo ninu ilana ọba jijẹ nilẹ Yoruba ti sọ awọn ọ̀ba di alailagbara.

“Oba ti ko ba lọ si ipebi ti di oba butter.”

O ni agba ofifo ni ọba ti ko ba ni awọn agbara alalẹ.

Ni erongba tiẹ, Oba Taiwo gbagbọ pe inu ọba ni agbara ọba wa, ti ko si nii sẹ pẹlu boya o wọ ipebi tabi ko wọ ọ.

Ẹwẹ lori ọrọ yii kan naa, Ọba Taiwo ni o yẹ ki ijọba ṣiṣẹ pẹlu awọn ọlọdẹ ilu, nitori pe awọn lo mọ gbogbo ibi kọlọfin to wa ninu igbo.

“Ti ijọba ba le ṣeto awọn ọdẹ ti yoo ma a ṣọ ilu, onikaluku a mọ ibi ti ina ti n jo wa.”

ọba Ogunleye sọ pe ki ijọba fi aaye gba ilu kọọkan lati ma a ṣọ ara wọn. O ni agbara ibilẹ Yoruba ṣi wa, a mọ “awa lao lo wọn bo ṣe yẹ”.

Ninu ọrọ ti ẹ naa, kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Abiodun Alamutu, sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti n ṣiṣẹ bayii pẹlu awọn araalu lati ri i pe eto abo duro daadaa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *