Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ Orijafunmi Awelewa, lọ tí ń janu lójú òpó Instagram láti gbé sẹ́yìn gbajúgbajà òṣèré olólùfẹ́ wọn, tó sọ̀kò ọ̀rọ̀ lu àwọn akẹ́gbẹ́ rẹ̀.
Àwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ yìí ló ní wọ́n fẹ́ràn láti má sanwó iṣẹ́ tí wọ́n bá bẹ akẹ́gbẹ́ wọ́n láti kópa nínú sinimá agbéléwò.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe kọ́ soju òpó instagram rẹ̀, “ṣe ẹrí àwọn akẹ́gbẹ́ wa nínú eré tíátà, wọ́n fẹ́ràn láti máa bá àwọn ènìyàn ṣe, tí wọ́n bá rí àǹfààní lọ́dọ̀ ẹni náà ní.
Ọmọ Iya mi jà f’órí rẹ̀. Awọ́n ènìyàn fẹ́ran láti lo ènìyàn, kì wọn sì já jù sílẹ̀ bí náírà márùn-ún àlòkù”
Orijafunmi ṣàlàyé pé kí gbogbo àwọn akẹ́gbẹ́ òun gbajumọ nǹkan tí yóò gbé oúnjẹ́ òòjọ́ wá sórí tábìlì wọ́n, nítorí lẹ́yìn ó rẹyìn, àwọn àti ẹbí nìkan ni yóò kojú nnkan tó bá jẹyọ.
Ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ló ti wá ń kín ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn pé, ọ̀rọ̀ Funmi Awelewa jána, àwọn òṣèré tíátà mìíràn pẹ̀lú wà lára àwọn tó gbàrùkù tí nǹkan ti Funmi sọ.
Díẹ̀ lára àwọn tó kín Funmi lẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ náà rèé