Home » Oyo PDP: Ẹgbẹ́ alábùradà pín sí méjì, igun Kan ta kété sí Seyi Makinde

Oyo PDP: Ẹgbẹ́ alábùradà pín sí méjì, igun Kan ta kété sí Seyi Makinde

O dabi ẹni pe ipilẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, nipinlẹ Ọyọ ti n mì bayii, to si ṣe e ṣe ki ẹgbẹ naa o tuka, pin kelekele.

Eyi KO ṣẹyin bi awọn agbaagba ẹgbẹ Kan ṣe kede pe, awọn ti da ẹgbẹ osẹlu naa si meji, abala Kan fun Gomina Seyi Makinde, ati abala keji fun awọn to fẹ ilọsiwaju ẹgbẹ.

Nibi ipade Kan ti wọn ṣe ni ilu Ibadan ni wọn ti kede pe inu awọn ko dun si bi Makinde ṣe n ṣe akoso ẹgbẹ naa.

Oriṣiriṣi awọn ẹsun ati aṣemaṣe si ni wọn fi ka si gomina lẹsẹ.

Lasiko to ba sọrọ lori igbesẹ wọn, ọkan lara awọn agba ẹgbẹ naa to yapa, Alhaji Nureni Adebayo Akanbi sọ pe aṣiyan patapata ni gomina Seyi Makinde jẹ fun ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ọyọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *