Sunday Igboho: Aráalé kan ní DSS fo ògiri wọ́lé ní nígbà tí wọn kò rí ìlẹ̀kùn já

Ọkan lara awọn eniyan to wa ni ile Sunday Igboho, to fi orukọ bo ara rẹ lasiri ti salaye ohun to sẹlẹ nigba ti awọn ikọ otẹlẹmuyẹ DSS ṣekọlu si ile Sunday Igboho ni ooru ọjọ naa.

Ẹni naa to ba ileeṣẹ iroyin Cable sọrọ wi pe, awọn to ṣe ikọlu naa wo aṣọ ologun Naijiria, ti wọn si wọ inu ile naa bi ẹni pe wọn mọ inu ati ode ile naa.

O ni nigba ti awọn to ṣekọlu naa de ẹnu ọna ti wọn ko si ri ṣi, ti wọn ko si le ja ilẹkun ẹnu ọna naa, ni wọn fo ogiri wọle sinu inu ile.

            

Ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ ni orisirisi ohun ija oloro ni wọn mu wa sibẹ, ti kii ṣe ti awọn eniyan lasan, amọ ti awọn ologun.

”N ṣe ni wọn yinbọn lakọ-lakọ si gbogbo ibẹ, lai wo ibi ti wọn n yinbọn lu.”

”Awọn agbebọn naa pọ de ibi pe ko si kọrọ ibi ti wọn ko duro si ninu ile naa, awọn ti wọn si wọle da gbogbo ile naa ru patapata.”

”Nigba ti wọn ko ri Sunday Igboho ninu ile, ni wọn bẹrẹ si ni yin ibọn lu awọn aworan rẹ to wa ni ẹgbẹ ogiri.

”Awọn ologbo ti wọn wa ni ile Sunday Igboho naa fi ara gba ọgbẹ ibọn, ti wọn si pa lara wọn, ki wọn to gbe awọn to ku lọ si ileeṣẹ DSS.”

Ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ ni awọn DSS to wa naa dabi ẹni pe wọn ni maapu ile Igboho to wa ni Soka, ti wọn ti ṣe ikọlu naa dani.

Agbẹnusọ fun Sunday Igboho ni eniyan meji ni ikọ DSS pa lasiko iṣẹlẹ naa, ti ọpọlọpọ si wa ni atimọle ọlọpaa.

Bakan naa ni wọn ko oogun ibilẹ ati awọn eroja miran ti wọn ba ninu ile Sunday Igboho, ko to di wi pe DSS kede wi pe wọn n wa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *