Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho jẹ ẹnikan ti ọpọ n wo gẹgẹ bi alagbara to kaato lati gbawọn eeyan silẹ lọwọ awọn afiya jẹni.
Idi niyii ti wọn maa fi n pe ni Igboho Oosa, ajijagbara ati ajafẹtọ ọmọniyan.
Eyi gan an lo jẹ ko wa lara awọn to n ṣe agbatẹru iwọde lati pe fun iyapa ati idasilẹ orilẹede Yoruba lara Naijiria.
lo jẹ fun ọpọ ọmọ Naijiria papaa julọ nilẹ Yoruba, bi ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣe raye wọ ile alagbara ajijagbara naa to wa lagbegbe Soka niluu Ibadan loru mọju Ọjọbọ.Bẹẹ ni ọpọ n beere pe nibo ni Igboho wa, ti ko fi lee koju awọn osisẹ DSS to wa ko awọn ọmọlẹyin rẹ lai bikita fun oogun to ni.
Bakan naa ni wọn ni niwọn igba to jẹ pe alagbara ni Igboho, ko se fi awọn oogun naa raga bo awọn ọmọ lẹyin rẹ, tabi ko ti lo diẹ fun wọn, ti ibọn ko fi ni le ran wọn.
Nipari, awọn ọmọ Yoruba kan wa n beere pe se ewe sunko fun Sunday Igboho ni lasiko tawọn osisẹ DSS fi wa, ni ko se duro koju wọn, ko si se wọn bii ọsẹ ti n soju.
Ọna lati wa idahun sawọn ibeere yii lo mu ka tọ agba alagbara kan nilẹ Yoruba lọ, ẹni to tun jẹ gbajumọ Babalawo ti ko se fi ọwọ rọ sẹyin.