Home » Super TV CEO Ataga: Chidinma ò gbudọ̀ kú o sátìmọ́lé Ọlọ́pàá o! Àwọn aṣòfin f’ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá

Super TV CEO Ataga: Chidinma ò gbudọ̀ kú o sátìmọ́lé Ọlọ́pàá o! Àwọn aṣòfin f’ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá

Bakan naa, ile aṣojuṣofin tun ni ki wọn ṣe iwadii ati ayẹwo finifini lori ẹsun naa ki wọn si ma ṣafihan arabinrin Chidinma kiri mọ tabi ki wọn maa gbaa laye lati ba awọn oniroyin sọrọ lori ọrọ ti wọn ṣi n ṣewadii rẹ lọwọ.

Ile aṣofin ni ki Ọga agba awọn ọlọpaa, Usman Baba “pe gbogbo awọn ọlọpaa ko ki wọn nilọ pe ko si atunṣe iru iwa ipa yii lori ẹtọ ọmọniyan ati gbigba awọn ti wọn ba fi panpẹ ofin mu laaye lati ba awọn oniroyin sọrọ.

Wọn n sọ eyi gẹgẹ bi ọkan lara awọn afẹnuko wọn nibi ijoko ile to waye lọjọ Iṣegun lẹyin ti wọn jọ pa ohun pọ lori ọrọ ti wọn lo gba amojuto kiakia ti aṣoju Tolu Akande-Sadipe mu aba rẹ wa to pe akori rẹ ni “Bi Ọlọpaa ṣe n tẹle ofin ijọba apapọ ati iwadi kikun lori iku oloogbe Ọ̀gbẹ́ni Usifo Ataga.

Gẹgẹ bi awọn aṣofin ṣe sọọ, eyi jẹ lati rii daju pe wọn ṣiṣẹ lori awọn ẹsun mii lọjọ iwaju bi eleyii.

Lafikun, ile aṣojuṣofin ni ọga agba ọlọpaa gbudọ rii daju pe arabinrin Ojukwu ti wọn fẹsun kan ko ku si ahamọ tabi pa ara rẹ nigba to n duro de idajọ rẹ gẹgẹ bo ṣe ti ṣẹlẹ sẹyin lori awọn ẹsun kan to ti kọja.

Ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹfa ọdun 2021 ni ileeṣẹ ọlọpaa Eko ṣafihan oju Chidinma nigba to jẹwọ pe oun lo n gun Ataga ẹni aadọta ọdun naa lọbẹ lọrun pa lẹyin gbọnmi sii omi o to.

Chidinma tun tun eyi sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ba awọn oniroyin kan sọ.

Ẹwẹ, ninu fidio kan to wa gba ori ayelujara kan lọjọ Aje ni arabinrin Chidinma Ojukwu ti bẹrẹ si ni sọ pe oun kọ loun pa ọga ileeṣẹ Super TV.

Nigba to da aba lọjọ Iṣegun, Aṣofin Akande-Sadipe muu wa si iranti ile pe lati igba ti ọlọpaa ti mu arabinrin Chidinma ni wọn ti n ṣafihan oju rẹ kiri ti wọn si n jẹ ko ba awọn oniroyin sọrọ lori ọrọ to wa di ohun ti wọn n gba bi ẹni n gba igba ọti lori ayelujara bayii ti awn oniroyin wa brẹ si ni pin ọrọ naa yẹlẹ yẹlẹ.

Gbogbo eleyi naa n ṣẹlẹ pẹlu pẹlu pe ọlọpaa ṣi n ṣe iwadii lọwọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *