Traditionalist Oba Ogun: Àwọn oníṣẹ̀ṣe ń fẹ́ kí ìjọba yọ ọwọ́ nínú Ọba yíyàn ní ìpínlẹ̀ Ogun

Wọn ni ki awọn aṣofin ọhun dawọ iṣẹ duro lori abadofin naa ti yoo fun ijọba lagbara lati maa ṣakoso bi wọn ṣe yan ọba nitori kii ṣe iṣẹ wọn.

Agbẹnusọ awọn oniṣẹṣe nipinlẹ ogun, Ifayemi Osunlabi sọ fun awọn akọroyin niluu Abeokuta pe ti abadofin naa ba le di ofin, yoo pa awọn etutu kan ti wọn maa n ṣe fun awọn to ba fẹ jẹ ọba ni ipinlẹ naa rẹ.

Osunlabi sọ pe ẹnikẹni to ba fẹ jẹ ọba ni lati tẹle gbogbo awọn alakalẹ iṣẹṣe to wa nilẹ lati igba iwasẹ wa.

O ni ti wọn ba ṣe aṣeyọri ninu gbigbe ofin naa kalẹ tan, yoo tẹ ẹtọ awọn oniṣẹṣe mọlẹ, o si ṣeeṣe ko da wahala silẹ laarin ilu.

“Ẹnikẹni to ba ti jẹ Ọba ti di igbakeji oriṣa, irufẹ ẹni bẹẹ si ni lati tẹle awọn aṣa ati iṣẹṣe kan to ti wa nilẹ tipẹtipẹ.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *