Home » wọn eeyan ilu Ajasẹ-Ipo rọ awọn afọbajẹ lati fi ẹni to yẹ sipo Olupo

wọn eeyan ilu Ajasẹ-Ipo rọ awọn afọbajẹ lati fi ẹni to yẹ sipo Olupo

Awon eeyan ilu Ajase-Ipo, nipinle Kwara ti ni ki awọn afọbajẹ ilu naa tete yan ẹni toyẹ sipo ọba ilu naa. 

Ninu ọrọ ti awọn eeyan kan ba wa sọ ni wọn ti sọ pe Omooba Taiwo Saliu Oniro Alebiosu lawon n fe gege bii oba tuntun niluu naa, wọn ni ọkunrin oniṣowo pataki naa ni ipo Olupo tiluu Ajasẹ-Ipo tọ si.

Awon to soro yii so pe ko si elomi-in to ye nipo yii ju Omooba Taiwo Oniro lo. Won ni omowe ni, to ti gbe loke-okun fun aimoye odun, to fi owo ti Olorun fun un tu ilu se ni Omooba Taiwo Oniro. Won lo da awon loju doba pe to ba dori ite awon baba nla re, opo ilosiwaju ati idagbasoke ni yoo my ba ilu.

Awọn eeyan yii sọ pe ṣaaju asiko yii ni Ọmọọba Taiwo to jẹ ọmọoye lati idile Oniro ti n lo ọla ati owo ti Ọlọrun fun un lati fi tun ilu Ajasẹ-Ipo ṣe,lara ohun to ti ṣe fifun awọn akẹkoo lanfaani ẹkọ-ọfẹẹ, fifi ina si gbogbo ilu, bẹẹ lo mọ ọgba yika itẹkuu ilu naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *