Home » Yoruba Nation: Ìrìn padà tẹ fún ìrìn, àwọn aláwo siwájú ìwọ́de láti kojú ọlọ́pàá l‘Eko

Yoruba Nation: Ìrìn padà tẹ fún ìrìn, àwọn aláwo siwájú ìwọ́de láti kojú ọlọ́pàá l‘Eko

Iwọde Yoruba Nation Rally to kọkọ ṣebi ẹni pe ko ni waye nilu Eko ti pada gbera sọ bayi

Ṣugbọn awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun ti fi omi ati afẹfẹ tajutaju tu awọn oluwọde naa ka.

Akọroyin wa to jabọ lati ibi iwọde naa nilu Eko sọ pe lọwọ aarọ ti oun debẹ niṣe lawọnb ọlọpaa kun iwaju aaye inaju Gani Fawehinmi ti ko si si oluwọde ni tosi.

Nigba ti yoo fi di nkan bi ago mọkanla ni Kọmisana ọlọpaa ipinlẹ Eko Hakeem Odumosu wa lati ba awọn akọroyin sọrọ.Bi o ṣe n ba awọn akọroyin sọrọ ni awọn oluwọde naa ba ṣadede ṣi wa, ti wọn si bẹrẹ si ni kọrin lorisirisi pe iya pọ to n jẹ awọn ni Naijiria.

Ariwo Yoruba Nation, Ooṣa ati bẹẹ bẹẹ lọ si lo gbode nibi iwọde naa ti waye, ti awọn oluwọde si n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba kuro lara ni Naijiria.Ki a to wi ka to fọ, awọn ọlọpaa ti gbe ọkọ nla wọn lati maa fi yin omi si awọn oluwọde ti wọn si tun wọn ka.

Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn oluwọde kan ti wọn si gbe wọn si inu ọkọ wọn ti wọn gbe wa.

Bakan naa ni iron ibọn n dun lakọ lakọ

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *