Buhari Oloto: Gbajúmọ̀ ọba tó lo sàá lágbo fàájì ìlú Eko fún ogójì ọdún ó le

Ebenezer Obey sọ pe iyalẹnu ni iroyin iku rẹ jẹ fun oun, to si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi alatilẹhin oun timọtimọ fun ọpọlọpọ ọdun.

Ọjọbọ ni iroyin iku Ọba Oloto, to tun jẹ gbajumọ nilu Eko, jade sita.

Nigba aye rẹ, oun ni Ọba alaye ilẹ Iguru, Aguda, Surulere nipinlẹ Eko.

Oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020 ni ọba naa pe ẹni ọgọrin ọdun.

inu oṣu naa paapaa ni wọn gbe ade le e lori gẹgẹ bi ọba.

Bakan naa ni iroyin sọ pe oun ni ọba akọkọ to jẹ, ni Aguda-Surulere.

Awọn olorin bi oloogbe Sikiru Ayinde Barrister, to si tun jẹ ọrẹ pẹlu rẹ, Wasiu Ayinde, Ebenezer Obey, ati bẹẹ bẹẹ lọ, naa maa n ki i ninu awọn orin wọn nigba aye rẹ

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *