Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa sọ fun BBC Yoruba pe ọpọ dukia ti iye rẹ ko din ni ọpọ miliọnu naira ni awọn janduku ọhun bajẹ lasiko ikọlu naa.
Lara awọn ohun ti wọn bajẹ ni awọn irinṣẹ ti wọn n lo ni ọọfisi, awọn ferese ọọfisi, to fi mọ awọn ọkọ ayọkẹlẹ atawọn dukia miran.
Ọga agba ileeṣẹ naa, Niyi Dahunsi ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin.
Dahunsi ṣalaye pe awọn ti fi isẹlẹ naa to awọn agbofinro leti, wọn si ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.