Home » Ẹ̀ṣọ́ Amotekun nawọ́ gán afurasí ajínigbé 43 ní ìpínlẹ̀ Ondo

Ẹ̀ṣọ́ Amotekun nawọ́ gán afurasí ajínigbé 43 ní ìpínlẹ̀ Ondo

Ẹ̀ṣọ́ ààbò Amotekun ní ìpínlẹ̀ Ondo ti nawọ́ gán àwọn afurasí mẹ́tàlélógójì fún ìwà ọ̀daràn lọ́kan-ò-jọ̀kan káàkiri ìjọb aìbílẹ̀ méjìdínlógún ní ìpínlẹ̀ náà.

Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tí àwọn kan jí àwọn ènìyàn kan gbé nínú ọkọ̀ bọ́ọ̀sì kan, tí wọ́n sì pa awakọ̀ ọ̀hún ní òpópónà Akunnu Ayere tó wà ní ààlà ìpínlẹ̀ Ondo àti Kogi.

Àwọn ajínigbé náà ni wọ́n fi ọmọ ọdún mẹ́ta kan sílẹ̀ nínú ọkọ̀ ero náà.

Nígbà tó ń fojú àwọn afurasí náà hàn ní iléeṣẹ́ àjọ náà tó wà ní Akure lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kejì ọdún 2024, ọ̀gá àgbà Amotekun Ondo, Akogun Adetunji Adeleye ní onírúurú àwọn ìwà ọ̀daràn ni wọ́n mú àwọn afurasí náà fún.

Adeleye ní àwọn mọ́kànlélógún nínú àwọn afurasí náà ló jẹ́ pé ìwà ìjínigbé ni wọ́n mú wọn fún.
Ó ní ohun tó yàtọ̀ ni bí àlékún ṣe bá àwọn afurasí tó jẹ́ pé ìwà ìjínigbé ni àwọn mú wọn fún.

“Bí ìlàjì àwọn afurasí tí a nawọ́ gán ló jẹ́ pé wọ́n ní ẹjọ́ láti jẹ́ lórí ìwà ìjínigbé, àwọn tó lé ní àádọ́ta ni a nawọ́ gán ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí ló ní ẹjọ́ láti jẹ́ jù.”

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé nítorí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó ti pọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ekiti ni àwọn afurasí ọ̀daràn náà fi ń sa wọ Ondo àmọ́ òun fẹ́ fi dáwọn lójú pé kò sí ààyè fún àwọn ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ Ondo.

Ó ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti dìde sí ìpèníjà ètò ààbò tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún àti pé agbègbè tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé ti wáyé ni àwọn ti mú ọ̀pọ̀ àwọn afurasí náà.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó ti móríbọ́ lọ́wọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé ni wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn mọ àwọn afurasí náà.

Adeleye tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀ afurasí náà ni wọ́n bá ohun ìjà lọ́wọ́ wọn tí wọn kò sì le sọ ohun tí wọ́n ń lò wọ́n fún.

Bákan náà ló fi kun pé gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Lucky Aiyedatiwa ti pa iléeṣẹ́ àwọn láṣẹ pé gbogbo àwọn tí wọ́n jígbé nínú ọkọ̀ èrò náà ni àwọn gbà kalẹ̀ láì farapa.

Ó ní àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó fi mọ́ àwọn ọlọ́pàá àti ọmọ ogun ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ láti ṣàwárí àwọn ènìyàn náà

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *