Home » Ọdọ wa ni awọn Kerubu ati Ṣẹlẹ ti ji ohun ti wọn n ṣe – Yeye Ọṣunronkẹ Olomitutu

Ọdọ wa ni awọn Kerubu ati Ṣẹlẹ ti ji ohun ti wọn n ṣe – Yeye Ọṣunronkẹ Olomitutu

Ẹ jẹ ka mọ yin daadaa

Emi ni Ọṣunronkẹ Akinọla Olomitutu, Igbo Olomu ni ikorodu ni mo n gbe

Bawo lẹ ṣe de idi Ọṣun?

O lagbara pupọ, oniṣowo pataki ni mi tẹlẹ, epo bẹntiroolu ni mo n ta, ti mo lorukọ nla nidii ẹ, ṣugbọn lojiji ni aisan nla kan ki mi mọlẹ, nibi ti mo ti n wa iwosan ni wọ ti sọ pe mo gbọdọ gba ooṣa yii,  mo yari kanlẹ pe ko si ohun ti mo fẹẹ fi ṣe, ṣugbọn nigba ti ẹmi fẹẹ bọ, mo pada gba a.

Mo lọọ sọ fun dẹrẹba ọga wa kan pe wọn sọ pe ki n gba odu-ifa, wọn beere ifa wo lo gba mi niyawo, ifa baba ti wọn mu mi lọ si ọdọ ẹ lo gba mi niyawo. Lẹyin ẹ mo tun ṣe agidi pe mi o ni i gba ooṣa yii, nigba ti mo tẹle ọrẹ mi kan wa si Igbo-Olomu, mo tẹlẹ lọ si ọdọ pasitọ kan, ohun ti baba to ni sọọsi naa sọ ni pe idi ooṣa ni ki n pada si, o ni ẹni to ba gbinyanju lati tọju mi yoo rọ lapa, rọ lẹsẹ ni.

Bi ẹ ṣe n wo mi yii, mo ṣe wolimọ fun ọmọ, musulumi ni mi tẹlẹ, Rafatu lorukọ mi. Nigba ti wọn ṣe oro fun mi tan ni Ibadan, ni mo lọ si ọdọ Adifala ti wọn ṣe oro fun mi nilu Eko yii, mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe nnkan mi n lọ siwaju si i.

Nigba ti mo kọkọ bẹrẹ, ọrẹ mi kan sọ fun awọn eeyan pe mo n tọrọ owo, mo jẹ ko ye wọn pe a gbele modi awo ni Ọsun, ki i ṣe onibaara. Ọmọ mi to jẹ aafaa lo lọọ sọ fun baba mi pe mo n ṣe awo, wọn beere lọwọ  ẹ pe iru awo wo ni mo ṣe, o ni mo ṣe awo Ọṣun, ohun ti baba mi sọ fun un ni pe mi o si ọna ya. Wọn ni iya to bi awọn lọjọ ti wọn wẹ ẹ  si ẹsin islaamu  lo dubulẹ aisan, to ku, baba mi sọ pe mi o si yan, wọn ni ki n lọọ gba oosa tile awọn, a si jọ lọ, wọn ṣe oro fun mi, o ṣi n jẹ fun mi.

Bawo lajọṣepọ ẹyi ati ọmọ yin to jẹ aafa yii?

Ajọṣepọ wa dan mọran, nitori pe dokita ni bayii, o ma n wa sibi daadaa, ṣugbọn eyi to jẹ obinrin ti ki i ṣe aafa gan-an ni ki i jẹ ounjẹ mi.

Ṣe ilana Ọṣun lawọn ọlọṣun to ma n tọrọ owo loju titi yii n ṣe?

 Ọpọlọpọ lo n fi ọṣun tọrọ baara, gbogbo awọn to n fi Ọṣun gba baara ohun to buru ni wọn n ṣe, Ọsun ki i gba baara, owo ko ku lọ, ko aarun lọ lawọn eeyan yii n gba, agbelejobi ni Ọṣun, iya mi ki i gba baara.

Ṣe loootọ ni pe apa kan eeyan, apa ẹja ni Ọṣun?

Bẹẹ ni, ṣugbọn ẹ ma jẹ ka sọrọ ju bẹẹyẹn lọ, a ko le tu asiiri aye nibi, iya mi awẹdẹ wẹriṣa, arẹwa obinrin.

Awọn kan sọ pe ilana yin lawọn ọmọ ijọ ṣẹlẹ ati kerubu n kọ pẹlu bi wọn ṣe lọọ ma n wẹ iwẹ itusilẹ leti omi. Ṣe loootọ ni?

Ẹ ṣeun, Ọṣun lo ni omi, ọrọ awọn ṣẹlẹ ko yatọ si ọrọ awa alaṣọ funfun, ko si ẹni to wa lati idile kan ti ko wa lati idile olooṣa, ẹsin ọlaju lo gba ọpọ nnkan lọwọ wa. Ni gbogbo ọjọ Tọsidee lawa naa ma n ṣe isin wa, awa la ni ẹmi ti awọn kristeeni ma n ṣe yen, wọn ji i lọdọ wa ni.

Awọn iṣẹ iwosan wo lẹ ti ṣe?

Wọn pọ daadaa, meloo ni mo fẹẹ ka, awọn ti mo ṣe isẹ fun pọ yanturu nilẹ yii ati loke okun, agbọmọla niyaa mi.

Awọn ohun eelo ni wọn fi ma n bọ Yemọja?

Egbo,  pẹpẹyẹ,  ọti, fanta                     

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *