Home » Oyo Covid-19 update, Delta variant of covid-19: Ó ṣeéṣe kí á kéde àwọn ìlànà tuntun láìpẹ́ – Ìjọba Oyo

Oyo Covid-19 update, Delta variant of covid-19: Ó ṣeéṣe kí á kéde àwọn ìlànà tuntun láìpẹ́ – Ìjọba Oyo

Agbẹnusọ gomina ipinlẹ ọhun, Taiwo Adisa lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Adisa ni iwadii ijinlẹ ti awọn onimọ ipinlẹ naa ṣe lo tete jẹ ki awọn kofiri ẹda arun tuntun ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe o ni lootọ ni awọn ti fidi rẹ mulẹ pe ẹda arun naa tuntun ti ran awọn eeyan kan ni ipinlẹ Oyo, afojusun awọn ni bi awọn yoo ṣe kapa rẹ ti ko si ni burẹkẹ si i.

O fi kun pe awọn ti bẹrẹ itanilolobo, awọn yoo si pada si awọn ilana ti wọn gbe kalẹ tẹlẹ lasiko ti arun ọhun kọkọ gbode kan lọna ati kapa rẹ.

Adisa ni “Awọn ohun ti an ṣe tẹlẹ ni a o pada si lati kapa ẹda tuntu yii.”

“O da bi pe arun naa ti n lọ lo jẹ ki ọpọ awọn eeyan turaka, ṣugbọn bayii ati bẹrẹ igbeṣe tuntun lati pana arun ọhun.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *