Hushpuppi news today: Wọ́n ní kí Kyari máá lọ ilé títí tí ìwádìí yóò fi parí lórí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Hushpuppi.

Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti ọga agba ileeṣẹ naa ni Naijiria, Baba Usman Alkali sọ pe ki wọn ṣe bẹẹ.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ọlọpaa ni Naijiria, Nigeria Police Service Commision, fi lede, eyii ti agbẹnusọ rẹ, Ikechukwu Ani buwọlu, o ni ileeṣẹ naa ti pinnu pe ki Kyari lọ joko sile titi di igba ti iwadii yoo pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Ṣaaju akoko yii ni ọpọ awọn ọmọ Naijiri to kọkọ n gboriyin fun Kyari, lori akitiyan rẹ lati kapa iwa ọdaran lawujọ.

ugbọn ajọ ọyẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika fẹsun kan pe o n ba gbajumọ onijibiti ori ayelujara, Hushpuppi dowo pọ.

Hushpuppi n jẹjọ nilẹ Amẹrika lori ẹsun pe o lu awọn eeyan kan ni jibiti, o si ti jẹwọ pe lootọ ni oun ṣe ohun ti wọn fẹsun rẹ kan oun.

I

wadii FBI fi han pe Hushpuppi fi owo ranṣẹ si Kyari, ko le lo ipo rẹ gẹgẹ ọlọpaa lati fi orogun Hushpuppi nidi iṣẹ gbajuẹ si atimọle.

wọn atẹjade ka lati ile ẹjọ ilẹ Amẹrika fi han pe iye owo ti Hushpuppi ti fio ọna ẹburu gba lọwọ awọn eeyan ti le ni milliọnu mẹtalelogun dọla.

Ẹwẹ, Kyari ti sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa ẹsun ti wọn fi kan oun.

Wayi, ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo n woye irufẹ igbesẹ ti ijọba naijiria yoo gbe lori ọrọ naa, boya wọn yoo fa le ijọba Amẹrika lọwọ ni tabi wọn ko ni ṣe bẹẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *