Wamu wamu ni ileeṣẹ ọlọpaa duro ṣaaju iwọde tawọn eeyan kan n gbero lati ṣe lọjọ Abamẹta tii ṣe June 12.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, SP Yemisi Opalola lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBc Yoruba.
”Kiki ni awọn ọlọpaa wa bi ibọn fawọn to ba fẹ da rogbodiyan silẹ lọjọ June 12 nipinlẹ Osun.
Gbogbo awọn ẹṣọ eleto aabo to fi mọ awọn sọja atawọn ẹṣọ eleto abo mii ni wọn ti parapọ ti wọn si n gbaradi fun iwọde June 12.
Koda awọn ẹṣọ eleto abo ti n wọde kaakiri ilu fun igbaradi ṣaaju ayajọ ijọba awarawa ni Naijiria.
Igbaradi to gbopọn wa nilẹ lati ọdọ awọn oṣiṣẹ eleto abo ṣaaju ọjọ Abamẹta yii.
Awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ eleto abo mii naa mọ nipa gbogbo bo ṣe n lọ nipa ifẹhonuhan tawọn eeyan kan fẹ ṣe.
Ṣugbọn o yẹ ka kọgbọn nipa iwọde EndSARS lọdun 2020 to mu ẹmi lọ,” agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye.
O ni ”kii ṣe pe ṣiṣe iwọde ko tọna labẹ ofin, ṣugbọn mo n fi asiko yii rọ awọn eeyan lati ma jẹ ki nkan bajẹ si ju ti tẹlẹ lọ.
Ọpọ eeyan lo fẹ fi iwọde boju lati wu oriṣiriṣii iwa ọdaran lọjọ June 12.”