Gbajumọ oṣere fuji nni, Alaaji Wasiu Alabi Ọdẹtọla Pasuma tawọn ololufẹẹ tun mọ si Ọga Nla fuji ti sọ pe ko ija tabi wahala kankan mọ laaarin oun ati gbajumọ oṣere fuji mi-in, Alaaji Saheed Oṣupa Akorede Okunọla ti wọn tun n pe Ọba Orin.
Nibi ayẹyẹ kan to waye niluu Apapa- Ajẹgunlẹ ti Pasuma ti lọọ kọrin lọsẹ to kọja yii lo ti sọrọ naa. Ninu ọrọ Paso ti wọn tun n pe ni Ijaya Fuji lo ti sọ pe ọrẹ oun daadaa ni Oṣupa ati pe ko si ede aiyede tabi aawọ kankan mọ laarin awọn.
Bi Pasuma ṣe kẹnu bọ ọrọ yii ni gbogbo awọn ero iworan to wa nibẹ kigbe nla,ti gbogbo wọn dunu pe ko sogun mọ, bẹẹ ni ko sọtẹ mọ laarin awọn irawọ fuji naa.
Lẹyin ti Ọga nla fuji sọrọ yii tan lo tun kẹnu bọ awọn orin Saheed Osupa, ni ariwo nla ba tun sọ ti gbogbo awọn ololufẹ ẹ awọn gbajumọ fuji naa fo soke fun ayọ, wọn ni inu awọn dun pupọ si ohun ti Pasuma sọ yii.