Home » Lagos Yoruba Nation rally: Ìwádìí wa fihàn pé kìí ṣe òkú tútú ni ọmọ tí wọ́n sọ pé a pa ní Ojota – Ọlọ́pàá Eko

Lagos Yoruba Nation rally: Ìwádìí wa fihàn pé kìí ṣe òkú tútú ni ọmọ tí wọ́n sọ pé a pa ní Ojota – Ọlọ́pàá Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti fesi si iroyin to n lọ pe ọta ibọn wọn lo pa Jumoke, ọmọ ọdun mẹrinla ni Ojota l’Eko lasiko iwọde Yoruba Nation.

Ninu atẹjade to fi sita, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa naa, Muyiwa Odejobi sọ pe ayederu iroyin patapata ni iroyin naa, ati pe o jẹ ọna lati da ibẹru ati wahala silẹ lọkan awọn eeyan rere to n gbe ni ipinlẹ Eko ati Naijiria lapapọ ni.

Ọsan ọjọ Satide ni iroyin jade pe ọta ibọn ọlọpaa lo pa ọmọbinrin naa lasiko to n ko ọja sita ninu ṣọọbu iya rẹ, ni Ojota, nitosi ibi ti iwọde Yoruba Nation ti waye.

Ọgbẹni Odejobi sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ko yin ọta ibọn kankan ni ibi iwọde to waye ni Ojota lonii (ọjọ kẹta, oṣu Keje).

O ni “ibi ti awọn eeyan ti ri oku naa jina si ibi ti iwọde ti waye. Lẹyin ileepo MRS to wa loju ọna to lọ si Maryland ni wọn ti ri.

“Odikeji ibi ti iwọde ti waye ni paapaa, to si jẹ pe ẹjẹ to wa lara oku naa ti gbẹ, eyi to tumọ si pe kii ṣe oku to ṣẹṣẹ ku.

Odejobi fikun ọrọ rẹ pe ayẹwo ti awọn ṣe si ara oku naa fihan pe ọgbẹ lan wa lara rẹ, to ṣeeṣe ko jẹ nkan ẹlẹnu ṣomu-ṣomu ni wọn fi gun.

O ni irọ ni iroyin naa, to si jẹ igbiyanju lati da wahala silẹ.

Bakan naa lo sọ pe iwadii yoo bẹrẹ ni kiakia lati mọ nkan to ṣokunfa iku ọmọdebinrin naa.

O si tun rọ awọn eniyan ipinlẹ Eko, lati ma a ba igbokegbodo wọn lọ lai bẹru.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *